Ọgbọ́n ló layé,
Ìmọ̀ ló nílé ayé pẹ̀lú,
Ọgbọ́n la fi ń darí ohun gbogbo,
Ọgbọ́n la fi ń rí lé ayé gbé pẹ̀lú,
Ẹni tó wà láyé tí kò lọ́gbọ́n lórí,
Irú wọn dàbí àpólà igi táa fi ń dáná,
Àwọn yoòbá tó ní ọgbọ́n ju agbára lọ ó purọ́,
Àwọn tó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ ló layé ò ṣèké,
Torí bóò bá lọ́gbọ́n,
Kò sí bóo ṣe fẹ́ gbélé ayé,
Ẹni tí ò lọ́gbọ́n á ṣebí òun lòun gbọ́n jù,
Bẹ́ẹ̀ kòròfo òfo nirú wọ́n jẹ́,
Bí o bá lágbára, tóo lówó lọ́wọ́,
Lálàì lọ́gbọ́n lórí, òfo ni gbogbo rẹ̀,
Torí bóò bá fọgbọ́n ṣe é,
Àṣìlò òun òpin yóò bá gbogbo ohun tó o ló o kó jọ,
Àmọ́ bí o ò bá lówó, tí o ò sì ní òkìkí,
Ṣùgbọ́n bí o bá lọ́gbọ́n,
Bó pẹ́, bóyá, Akólòlò rẹ yóò pe baba,
Báyé bá ń j'áyé,
Ọgbọ́n òun ìmọ̀ ló jogún ayé,
Ọgbọ́n ló borí ohun gbogbo,
Ẹni tí ò lọ́gbọ́n kùnà làákàyè,
Ta fi ń gbélé ayé,
Ẹni tí ó lọ́gbọ́n lórí,
Oun gbogbo pátá ló ní.