Loading
Ọgbọ́n ló layé,Ọgbọ́n la fi ń darí ohun gbogbo
Ọgbọ́n ló layé, Ìmọ̀ ló nílé ayé pẹ̀lú, Ọgbọ́n la fi ń darí ohun gbogbo, Ọgbọ́n la fi ń rí lé ayé gbé pẹ̀lú, Ẹni tó wà láyé tí kò lọ́gbọ́n lórí, Irú wọn dàbí àpólà igi táa fi ń dáná, Àwọn yoòbá tó ní ọgbọ́n ju agbára lọ ó purọ́, Àwọn tó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ ló layé ò ṣèké, Torí bóò bá lọ́gbọ́n, Kò sí bóo ṣe fẹ́ gbélé ayé, Ẹni tí ò lọ́gbọ́n á ṣebí òun lòun gbọ́n jù, Bẹ́ẹ̀ kòròfo òfo nirú wọ́n jẹ́, Bí o bá lágbára, tóo lówó lọ́wọ́, Lálàì lọ́gbọ́n lórí, òfo ni gbogbo rẹ̀, Torí bóò bá fọgbọ́n ṣe é, Àṣìlò òun òpin yóò bá gbogbo ohun tó o ló o kó jọ, Àmọ́ bí o ò bá lówó, tí o ò sì ní òkìkí, Ṣùgbọ́n bí o bá lọ́gbọ́n, Bó pẹ́, bóyá, Akólòlò rẹ yóò pe baba, Báyé bá ń j'áyé, Ọgbọ́n òun ìmọ̀ ló jogún ayé, Ọgbọ́n ló borí ohun gbogbo, Ẹni tí ò lọ́gbọ́n kùnà làákàyè, Ta fi ń gbélé ayé, Ẹni tí ó lọ́gbọ́n lórí, Oun gbogbo pátá ló ní.
Wisdom is what rules the world, Knowledge is also the foundation of the world, We use wisdom to guide everything, We use wisdom to live in the world too, A person in the world without wisdom, Is like a piece of wood used for fire, Those who say wisdom is greater than strength are lying, Those with wisdom and knowledge own the world without deceit, Because if you have wisdom, You will surely live well in the world, Someone without wisdom will think they are the wisest, But they are empty and void, If you have strength and wealth, Without wisdom, it is all meaningless, Because if you do things with wisdom, Misuse will bring an end to everything you have gathered, But if you don't have wealth, nor fame, Yet if you have wisdom, In time, your wisdom will be recognized, As the world enjoys life, Wisdom and knowledge inherit the world, Wisdom conquers everything, Someone without wisdom fails in understanding, Which is used to live in the world, Someone with wisdom, Has everything completely.